SpyLoaded Forum









News


Author Topic: ORIKI IDILE AGBOLE OGÁNLA ILU OSOGBO  (Read 1043 times)

Offline Morayo

  • Forum Administrator
  • Hero Member
  • ****
  • Posts: 12706
ORIKI IDILE AGBOLE OGÁNLA ILU OSOGBO
on: October 26, 2025, 07:38:09 AM



ORIKI IDILE AGBOLE OGÁNLA ILU OSOGBO.

1. OMO OLÁNI OKÁ, OJOLÁ OLUMÒ LÁPÀ
LÁNIOKA OMO AGUN BÍ IGBA AGOGO
TÈ TÈ HUN-Ò TÈ LÁPA
OLUMOMÍ OMO OKÁ ŃLÁ ELÉREBE
AGBÀ DJOLA OMO ERÈ LÁPA
GBÓKA SERÉ OMO ONÍNÁ EÉSAN
MO FI AIKO BAWON JÓ BÙ LÀ LÁPÀ
TALÓ SO PÉ OJOLA KONÍLÉ?
TALO LABÉ ILOSÙN?
TALO LABE EHÓLO?
TALÓ LÀBATÁBÚTÚ BABA ODÒ KÓDO?
TALÓ LADÁGÚN BABA OMI TỐ TẾJÚ GBEREGEDE?
NÍGBA TÓJÒLÁ KÒ SÍ NÍLE
NWON JOYE MÉTA DUN NÌNÍ, NÍ PÓPO AFIN
WÓN FI OKÁNLÁ JE JAGUN
WON FI ABIRUSÓRO JE ELÉMOSO ORA
WÓN FI SEBÉ JE MOYEMÍ WÒ LÁPA
BOO BÁ YÈMÍWÒ LÁPA, MAA TUSIE LÓJÚ, MAA TUSIE LENU,
MAA SE SE AGBON ISALE WORI-WORI.
OLÚMOMÍ OMO-OBÁ TÍ GBÓLAYAN GENGE

AITO LOWOWO NI NWON NFI PA EJO LÓKOKAN
BÍ OKÁNLÁ BÁ SÍWÁJÚ, TÍ PARAMOLE TELE
KÍ ERÈ MÓ WÓ RÌRÌ BÒ LỆHÌN WỌN, KÍ SÈBÉ KO TELE
TALÓ LE DÚRÓ DE OMO EJÒ LÁÀLÀ
TÍ OMO EJO BÁRIN PAPO
TALÓ LEBÉ KONDO TI OKÁ LÓRÍ?
TALÓ LEBÉ KUMO TOMмо OMO EJO LÉHIN?
GBÁLE GBALE APA, KÉNIKÉNI MỌ GBA IRAWE
E JÉ KI OKÁ ŃLÁ ILÉ WA KO MÓ RÍBI KÓ OMO WERE JE

NILE NINI ORA
OMO AGBÓLÚ OKÁ SE EBO
AGBA EJÒ YANU PAKA-PAKÀ LÁPA
TÍ ABA NRE IBI, AMÓTORO ASO MÚ RE IBI
BÍA BÁ NRE AJO, AMOTORO BATA MÚ RE AJO
OLÚMOMÍ, LÁNIÓKÁ, TANI YOO TORO ASO LÓWO RE?

3. OSÁN PANGANRÍN GANRÍN
KENIKÉNI MÓ RIN ODE LÁNI-OKÁ LO
BI OORUN BAKAN ATÀRÍ GBON-GBÓN-GBON
KÉNIKENI MÁRIN ODE LÁNIÓKÁ LỌ
NÍLÉ OJO LÁ OLÚMÒ LÁPÀ
GBÓKÁ SERÉ OMO ONÍNÁ EÉSAN
AFAI KÒ BÁWON JÓ BÙ LÀ LÁPÀ
EYIN LOMO OKA NLÁ ELÉREBE
OLUMOMI HUN-O-WỆ LÓDO, TÍMO BÁ WE LODÒ HUN-KO-RÍ
BABA ENI TOLE KÓ MI LÁSO LO
NÌNÍ NÌ MÍ, NINI NI IWO, AWA LOMO ERE LÁPA.

4. OMO ILOKO ARELU, OMO AJÓBA LÉLE,
TETE NKÒ TÈ NÍ ILOKO, OTÚN ILOKO TI MÚ IDÀ O DÌ ÈLE
OSÌ ILOKO TI MÚ IDA O DÍERO
AGBEDÉGBÉDÉ ILOKO TI MÚ IDÀ Ó DI IBÉ OMO LÓRÍ
ONISÉ IBU OMO AJÓBA LÉLE, OGÀN LÁ KÓLÉ KAN ÀRÀ
Ó KOJU RE SÍ ENIKAN OYUN,
Ó KO BOOPÉ O KOJU RE SÍ OLÚODE.

WRITTEN BY:-
'KUNLE AJIROWO OSENI AKEWI
07039619961, 09067945740, 08180482631


DOWNLOAD IMAGE COPY 1

DOWNLOAD IMAGE COPY 2

Oriki oganla1

Oriki oganla2










TAG:





 

With Quick-Reply you can write a post when viewing a topic without loading a new page. You can still use bulletin board code and smileys as you would in a normal post.

Note: this post will not display until it's been approved by a moderator.
Name: Email:
Verification:
"5 eggs" Multiply By "4 eggs" Is what ?:


Close
SimplePortal 2.3.6 © 2008-2014, SimplePortal